Ipele kẹrin (400level) ni wọn sọ pe Damian wa ni fasiti ọhun lasiko to lu ọrẹbinrin rẹ, Justina toun naa wa ni ipele kẹta (300level) ni fasiti naa pa.
Ẹkọ nipa imọ ẹrọ ti epo rọbii (Petrochemical Engineering) ni wọn sọ pe Damian n kọ nipa rẹ ni fasiti ọhun, nigba ti Jusina n kẹkọọ nipa Biochemistry.
Inu oṣu Kẹwaa, ọdun 2023 ni wọn sọ pe Damian, ọmọ ọdun mẹrindinlọgbọn naa lu ọrẹbinrin rẹ ọhun pa.
Nigba to n gbe idajọ kalẹ lọjọ Ẹti, Furaide, oni, Onidajọ Chiwen Nsirim Nwosu sọ pe awọn ẹri to tako Damian, eyi to tẹ ile-ẹjọ lọwọ fidi mulẹ, to si kọja ohun ti wọn le da ọwọ bo mọlẹ, fun idi eyi, o sọ pe iwa ti ọmọkunrin naa hu, tọ si idajọ iku.

No comments:
Post a Comment