Anikẹ Gbadebọ
Ajọ iṣọkan agbaye to n ṣe iranwọ fun ohun to nii ṣe pẹlu awọn ọmọde lagbaye, UNICEF ti gbe oṣuba kare fun ipinlẹ Kwara lori ọna ti wọn n gba ṣe agbelarugẹ fun eto ẹkọ.
UNICEF sọ pe ipinlẹ Kwara yege ninu ilana idagbasoke eto ẹkọ igbalode, nipa awọn agbekalẹ ati ilana to pe ye, fun ọjọ iwaju awọn ogo wẹẹrẹ.
Ninu lẹta ti ajọ naa kọ ranṣẹ si Gomina AbdulRahman AbdulRazaq, nipasẹ Kọmiṣanna feto ẹkọ, Ọmọwe Lawal Olohungbebe, wọn gbe oriyin fun ijọba Kwara fun bi wọn ṣe tayọ ilana eto ẹkọ igbalode labẹ eto ti wọn pe ni Nigeria Learning Passport (NLP), eyi ti wọn ṣe ifilọlẹ rẹ lọdun 2024.
UNICEF jẹ ko di mimọ pe ipinlẹ Kwara ti kọja ẹgbẹrun lọna ọrundin-laadọta (55,900) lori ikanni, leyi to fi han pe ida ọtadinlọọdunrun ni wọn wa ninu afojusun akẹkọọ ẹgbẹrun lọna ogun ni ipari ọdun 2025.
Wọn fidi rẹ mulẹ pe bi kii ba a ṣe ifarajin Gomina AbdulRahman AbdulRazaq lati mu idagbasoke ba eto ẹkọ, aṣeyọri le ma waye.
Wọn ni awọn ilana gomina ti gbe ipinlẹ Kwara si ipo adari ninu ilana eto ẹkọ igbalode lorileede Naijiria.

No comments:
Post a Comment