Aarẹ Bola Ahmed Tinubu ti yan alaga ẹgbẹ awọn gomina ilẹ Naijiria, Gomina AbdulRahman AbdulRazaq tipinlẹ Kwara gẹgẹ bi ọkan lara awọn igbimọ ti yoo maa ri si yiyanju aawọ to ba n dide ninu ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC.
Ilu Eko ni Aarẹ Tinubu ti gbe aṣẹ naa kalẹ, bi wọn ṣe n gbaradi lati wọnu gbogbo eto idibo ọdun 2027.
Gomina ipinlẹ Yobe, Mai Bala Buni ni alaga igbimọ ọhun, nivba ti oludamọran pataki lori eto ofin tẹlẹ, Muiz Banire jẹ akọwe ati ọmọ ẹgbẹ.
Lara awọn ọmọ igbimọ yooku ni Sẹnetọ Adamu Aleiro; Gomina Hope Uzodimma tipinlẹ Imo; to fi mọ awọn gomina bii Hyacinth Alia (Benue), Umar Namadi (Jigawa), Bassey Otu (Cross River), Abiodun Oyebanji (Ekiti) ati Sheriff Oborevwori (Delta).
Awọn gomina miran ni: Uba Sani (Kaduna), Siminalayi Fubara (Rivers); Minisita Adegboyega Oyetola, Bello Matawalle, ati Yahaya Bello tipinlẹ Kogi tẹlẹ.
No comments:
Post a Comment