AbdulRazaq ti mu ọpọ ileri ipolongo oṣelu ṣẹ ni Kwara - Awọn alakoso fontẹ lu gomina - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, December 25, 2025

AbdulRazaq ti mu ọpọ ileri ipolongo oṣelu ṣẹ ni Kwara - Awọn alakoso fontẹ lu gomina


...Fifi ipa rere manigbagbe lelẹ lo jẹ mi logun - AbdulRazaq 

Kọmiṣanna feto iṣẹ ode nipinlẹ Kwara, Abdulquawy Olododo ti sọ pe pupoọ ninu awọn ileri ti Gomina Abdulrahman Abdulrazaq ṣe lo ti mu wa si imuṣẹ.

Olododo lo fidi ọrọ naa mulẹ laipẹ yii nibi ipade awọn agbaagba ati alẹnulọrọ lẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC to waye niluu Ilorin, ipinlẹ Kwara.

Nibẹ ni wọn ti  fontẹ lu Gomina AbdulRazaq gẹgẹ bi olotitọ to n fẹ ilọsiwaju, ti wọn si ṣe afihan awọn akanṣe iṣẹ ti iṣakoso naa ti ṣe pari, ati awọn eyi to n lọ lọwọ.

Olododo jẹ ko di mimọ pe iṣakoso Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ni ọpọ iṣẹ akanṣe to ti pari, awọn eyi to n lọ lọwọ, to fi mọ awọn iṣẹ opopona ti wọn mu wa, ju ti awọn iṣakoso mẹta to ti waye kọja lọ laaarin ọdun 1999 si asiko ti gomina gbajọba.

O ni iṣakoso asiko yii ti pari opopona kilomita mejilelọọdunrun (302.4kms) laaarin ọdun 2019 si asiko yii, to si tun ni opopona kilomita 275.25km to n lọ lọwọ, ati opopona 209.7km to n lọ lọwọ labẹ iṣakoso RAAMP.

Bakan naa lo fi kun un pe opopona ti wọn gbe kalẹ labẹ akoso owo ori, to n lọ lọwọ jẹ (294km), ti apapọ gbogbo rẹ si jẹ 871.65km.
 
“Laaarin ọdun 1999 si 2019, akọsilẹ opopona ti a ni labẹ iṣakoso mẹta jẹ 651.2km; awọn eyi lo waye lasiko  Mohammed Lawal, Abubakar Bukola Saraki, ati Abdulfatah Ahmed, to fi mọ opopona tijọba apapọ Chickanda ṣagbatẹru rẹ labẹ iṣakoso Sẹnetọ Bukola Saraki.

"Nigba ti ẹ ba ṣe agbeyẹwo gbogbo rẹ, o foju han pe awọn eyi ti Gomina AbdulRazaq dawọ le kọja awọn nnkan to ba nilẹ,”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI