Gbajugbaja oniṣowo kan lagbegbe Owode Ẹgba to wa nijọba ibilẹ Ọbafẹmi Owode, ipinle Ogun, Ọgbẹni Johnson Ajibọla Akindele ti sọ pe ki ẹnikẹni ma ṣe gba iroyin ẹlẹjẹ ti wọn n gbe kaakiri nipa oun gbọ, bi ko ṣe pe ọrọ ibanilorukọ jẹ lasan ni.
Akindele lo sọrọ naa lasiko to n ba AWIKONKO sọrọ niluu Abẹokuta, to si ni loun kii ṣe oloṣelu, toun ko si le da si ọrọ oṣelu to n lọ nijọba ibilẹ naa.
Laipẹ yii ni iroyin kan jade sita lori ayelujara wi pe Akindele n wa ọna lati gbe wahala dide sinu aye ọkan lara awọn gbajumọ oloṣelu nijọba ibilẹ Owo Ẹgba, ẹni ti wọn pe ni Ọnarebu Adekunle Lateef.
Iroyin ori ayelujara naa sọ pe wọn ri fọnran kan nibi ti Adekunle ti n sọrọ Ọnarebu Adekunle fun ẹnikan lori foonu pe awọn maa ṣiṣẹ pa a, ati pe awọn ko ni jẹ ko ta ilẹ mọ lagbegbe naa.
Oniruuru ẹsun ni wọn fi kan Adekunle ninu iroyin naa, ṣugbọn toun naa si ti sọ pe irọ to jinna si otitọ ni wọn pa mọ oun.
Nigba to n sọrọ, o ni “Ọrọ ti Lateef n gbe kaakiri wi pe mo pe ẹnikan, ti wọn n sọrọ wahala, gbogbo ohun ti wọn n sọ yii ti le lọdun kan. O kan n wa ọna lati dabaru oju ọna to lọ di pa ni.
“Wọn ti mu Lateef wa bẹ mi, ti mo si ti gba ẹbẹ lori rẹ. O ṣi jẹ mi lowo, mo si ti gboju fo o da. Ilẹ to n sọrọ rẹ yi, o jinna si kilomita marun si abule. Oṣelu lo n gbiyanju lati lo fun wa, ati pe onilaakaaye ni gbogbo awọn aṣoju ijọba to wa ba wa da si ọrọ naa, wọn si maa gbe igbesẹ to yẹ lori rẹ.
“O sọ pe mo fẹẹ ba oun ati APC lorukọ jẹ, emi ti mi o kii ṣe oloṣelu, nko si du ipo, nitori pe nko nilo ipo. Owo ilaji ilẹ ni Lateef san, ko san ilaji to ku, o si wa lọ di ọna ti awọn eeyan n gba pa, idi ree to fi n purọ kaakiri, nitori ko fẹẹ ṣe atunṣe.”
O wa rọ Lateef gẹgẹ bi oloṣelu maa ṣe awọn nnkan ti yoo mu irọrun de ba araalu, kii ṣe eyi ti yoo pa araalu lara.
No comments:
Post a Comment