AbdulRazaq kọju ija sawọn tọọgi to da iwọde awọn obinrin ru n’Ilọrin - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, December 30, 2025

AbdulRazaq kọju ija sawọn tọọgi to da iwọde awọn obinrin ru n’Ilọrin

Gomina AbdulRahman AbdulRazaq tipinlẹ Kwara ti kọminu lori bi awọn tọọgi kan ṣe da iwọde ifẹhonuhan alalaafia ti awọn obinrin ṣe niluu Ilọrin laipẹ ru, to si ni ki ileeṣẹ ọlọpaa bẹrẹ iwadii lati rọwọ to gbogbo awọn to mọ nipa ikọlu naa.

AbdulRazaq ninu atẹjade ti akọwe iroyin rẹ, Rafiu Ajakaye fi sita lọjọ Aje, lo ti bu ẹnu atẹ lu ikọlu ti wọn fi da iwọde naa ru.

Awọn obinrin kan la gbọ pe wọn ko ara wọn jọ lọ si ẹnu ọna abawọle ile ijọba to wa niluu Ilọrin lasiko isinmi ọdun Keresimesi to waye laipẹ yii, ti wọn si n fẹhonuhan si ijọba.

Lojiji ni wọn sọ pe awọn tọọgi kan lọ sibẹ lati tu wọn ka, ti ọrọ si di ‘ẹni ori yọ, o di ile’ lọjọ naa.

Ọpọ awọn olufẹhonuhan ọhun la gbọ pe wọn farapa, koda ti wọn sọ pe awọn tọọgi ọhun tun lu wọn lalubami.

Nigba to n sọrọ, gomina jẹ ko di mimọ pe iwa ti ko tọna lawọn tọọgi naa hu, nitori pe gbogbo eeyan lo lẹtọọ labẹ ofin lati fi ẹhonu han.

“Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti fi ẹdun ọkan han si fọnran kan to ṣafihan ibi ti awọn tọọgi ti lọ ṣe ikọlu si awọn obinrin to n fẹhonu han lasiko isinmi Keresimesi, eyi ti wọn ṣe nitosi ẹ nu ọna abawọle ile ijọba ti wọn ti n ṣe atunṣe rẹ lọwọ niluu Ilọrin,” Gomina AbdulRazaq sọ bẹẹ.

O sọ siwaju pe: “Ifẹhonuhan alalaafia jẹ ẹtọ labẹ iṣẹjọba awarawa. Awọn obinrin naa wa labẹ ẹtọ wọn lati fi erongba ati ẹhonu wọn han. A wa n sọ ọ sita bayii pe a ko mọ ohunkohun nipa ikọlu naa, nitori pe ko tọka si ohun ti a duro fun gẹgẹ bi ijọba.

“A n pe awọn ọlọpaa lati wa awọn to ṣe ikọlu naa kan, ki wọn si fi wọn j’ofin.”

O wa sọ pe ijọba oun n gbe igbesẹ lati rii pe ẹmi ati dukia araalu wa labẹ aabo to jẹ ijọba oun logun, ati pe awọn ṣẹṣẹ ṣe ayẹyẹ fun awọn aṣogbo tuntun ni, lati daabo bo inu igbo to wa ni Kwara.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI