Akọlukọgba oriire! Wọn tun fi awọọdu nla da Akewejẹ Ile-Ọlọfa, Fafoluyi lọla - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, December 29, 2025

Akọlukọgba oriire! Wọn tun fi awọọdu nla da Akewejẹ Ile-Ọlọfa, Fafoluyi lọla


Ọrọ Yoruba ti wọn maa n sọ pe ‘Yin-ni-yin-ni, k’ẹni o ṣe ‘min-in’ lo mu ki gbogbo ọmọ ẹgbẹ Aran-Orin Progressive Union ati Alaran in Council fi aami ẹyẹ nla da Akewejẹ tiluu Ile-Ọlọfa, Olayinka Fafoluyi lọla.


Fafoluyi to jẹ amugbalẹgbẹ pataki fun Gomina AbdulRahman AbdulRazaq lori eto iroyin igbalode ni wọn gbe oṣuba kare fun lori awọn ipa to n ko ninu idagbasoke ipinlẹ naa, paapaa ilu Aran-Orin.


Diẹ lara awọnm akanṣe iṣẹ idagbasoke ti Fafoluyi dawọ le ni wọn pe ni ‘Light Up Aran-Orin’ iyẹn ni ti ina agboorin igbalode to n ṣagbatẹru rẹ kaakiri ilu naa, ṣiṣe omi ẹrọ igbalode fun irọrun araalu ati kikọ ilegbe awọn agunbanirọ to pe ni ‘ABDULRAHMAN ABDULRAZAQ CORPERS’ lodge’.


Nibi ayẹyẹ ọlọdọọdun ti Ojude Aran to waye laipẹ yii ni wọn ti fi aami ẹyẹ naa da Fafoluyi, tọpọ tun n pe ni Solace lọla.


Ọpọ awọn to wa nibẹ ni wọn fidi rẹ mulẹ pe aṣoju gidi to n gbe ogo ilu naa ga ni Solace, ti wọn ko si kabamọ pe o wa ninu ijọba.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI