Idunnu lo ṣubu lu ayọ awọn opo ti ko din ni ọgọrun kan kaakiri ipinlẹ Ogun nigba ti gbajugba oniṣowo ilẹ ati dukia nipinlẹ naa, Ọmọwe Babatunde Adeyẹmọ fi ẹbun ọdun ta gbogbo wọn lọrẹ, to si tun fun awọn miran ni anfaani eto ẹkọ.
Yatọ si awọn ẹbun wọnyi, Ọmọwe Adeyẹmọ tun gbe eto ayẹwo ilera ọfẹ kalẹ fun ọpọ awọn eeyan, lati le jẹ ki awọn araalu wa ni ilera pipe.
Ọmọwe Adeyẹyẹ nigba to n lo ajọ oluranlọwọ rẹ, ‘Ọkọ Opo’ lati fi ṣe awọn iranwọ naa, lo ti gba gbogbo awọn alẹnulọrọ laaarin ilu lati gbe iru igbesẹ bayii, to si ni erongba oun lati di alafo to wa laaarin olowo ati mẹkunnu.
Kii ṣe igba akọkọ ree ti ajọ Ọkọ Opo yoo maa ṣe iranwọ fawọn araalu, paapaa awọn opo, lati bi ọdun mẹta si mẹrin ni alakoso ileeṣẹ naa, Ọmọwe Adeyẹmọ to tun jẹ agba akọroyin nipinlẹ Ogun ti n lo ajọ naa fun iranwọ.
Ọkan lara awọn to jẹ anfaani yii, Arabinrin Titilọpẹ Adewunmi to jẹ iyawo oloogbe Wale Adewale to ti figba kan ti jẹ alaga ẹgbẹ aṣojukọroyin nipinlẹ naa fi idunnu rẹ, to si gbe oṣuba karẹ fun ajọ Ọkọ Opo.
Arabinrin Adewunmi jẹ ko di mimọ pe ibi ti wọn sin ọkọ oun si loun n fomije lọ, nigba ti ajọ Ọkọ Opo ranṣẹ pe oun, ti wọn si ṣe oore manigbagbe fun akọbi oun lobinrin; o ni wọn fun ọmọ naa ni eto ẹkọ ọfẹ, bẹẹ ni wọn tun n fun un lowo oṣu fun oṣu mẹfa gbako lai ṣiṣẹ kankan fun wọn.
Obinrin naa sọ pe yatọ si eyi, ajọ naa tun gbe eto ilera ọfẹ kalẹ foun ni eyikeyi ile iwosan toun ba lọ lati gba itọju. O ni latigba ti ajọ naa ti n ṣe iranwọ foun ati awọn ọmọ, ni igbesi aye oun ti yi pada, to si ni akọbi oun naa ti wa nile-ẹkọ fasiti FUOYE to wa niluu Ọyẹ Ekiti, ipinlẹ Ekiti
Nigba toun naa n sọrọ, alakoso agba ajọ Ọkọ Opo, Ọmọwe Adeyẹmọ to tun jẹ oludasilẹ ileeṣẹ Pelican Valley Nigeria Limited to n ta ilẹ sọ pe iranlọwọ ṣe pataki, nitori pe ọpọ eeyan lo nilo iranlọwọ.
Agba akọroyin naa sọ pe erongba oun ni lati lo gbogbo nnkan toun ni, lati maa fi ṣe iranwọ fawọn alaini kaakiri agbegbe toun ba ti ba ara oun.
“Ẹnikẹni ti iwọ ba n’ipa lati ṣe iranlọwọ fun, oun naa ni ẹnikeji rẹ, tọju ẹ,” Ọmọwe Adeyẹmọ sọ bẹẹ.
“Latigba ti a ti bẹrẹ ajọ Ọkọ Opo ti kii ṣe ti ijọba la ti n ro awọn opo lagbara, bẹẹ si la ti ṣiṣẹ tọsan toru lati lo gbogbo ohun ti a ni lati mu idunnu ba ọpọ awọn opo ti wọn ti sọ ireti nu.
“Oniruuru ipa la ti ko, to si n mu mi ranti nigba ti mo n woye awọn aṣeyọri wa, eyi to n mu mi ranti awọn ipinnu wa nigba ti a bẹrẹ ajọ yii. Mo nigbagbọ pe a tun ṣi maa ṣe ju bayii lọ.”


No comments:
Post a Comment