Gomina ipinlẹ Osun, Ademola Adeleke ti kede sita pe ẹgbẹ oṣelu Accord loun gba lọ bayii, pẹlu erongba lati jade du ipo gomina lẹẹkeji.
Ọjọ Iṣẹgun ni Adeleke sọ fawọn akọroyin nipinlẹ naa ẹgbẹ oṣelu naa loun ri, gẹgẹ bi ẹgbẹ to le gbe oun de ipo gomina pada lẹẹkeji, lẹyin ti ẹgbẹ PDP toun wa tẹlẹ ti fọ si wẹwẹ.
Gbọngan Banquet to wa ninu ile ijọba lo ti sọrọ naa, niwaju awọn agbaagba ẹgbẹ oṣelu Accord l'Abuja ati nipinlẹ naa.
“Oṣu kan le diẹ sẹyin ni mo ti darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu Accord, iyẹn lọjọ kẹfa, oṣu Kọkanla, ọdun 2025, lati dije du ipo gomina lẹẹkeji lọdun 2026. Eyi lo waye lẹyin ọpọlọpọ ọsẹ ti mo fi ṣe iwadii ati lati ba awọn agbaagba, to fi mọ alẹnulọrọ sọrọ lati mọ erongba wọn,” Adeleke sọ bẹẹ.
“Awọn alẹnulọrọ ati olugbe ipinlẹ Osun mọ nipa idi ti a fi n gbe igbesẹ yii. A ni erongba lati du ipo gomina lẹẹkeji labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Accord lati le pari saa ijọba to dara, eyi ti a n ba lọ, ati iṣejọba awarawa to ni itẹwọgba nile-loko.
“A lọ fun ẹgbẹ oṣelu Accord nitori pe erongba ati afojusun ti a ni lọ ni ibamu pẹlu igbe aye irọrun fawọn araalu ati ẹtọ awọn oṣiṣẹ.”
Bakan naa lo sọ pe ilana ẹgbẹ Accord lo wu oun lori, leyi to jẹ koun darapọ mọ ẹgbẹ naa, to si loun nigbagbọ pe ẹgbẹ naa yoo jawe olubori ninu eto idibo gomina to maa waye loṣu Kẹjọ, ọdun 2026.

No comments:
Post a Comment