Aarẹ Adetola sọ pe ipa ribiribi ti Ọọni ti ko, ti jẹ ki ẹya Yoruba maa gbarada kaakiri agbaye, to si ti gbe wọn si ipo ọlọla nibikibi ti wọn ba de lagbaye.
Ọjaja keji lo n ṣayẹyẹ ọfun mẹwaa to gba ade gẹgẹ bi Ọọni Ile-Ifẹ, ti gbogbo awọn olulufẹ ati afẹnifẹre si n ba a yọ.
Ninu atẹjade ti alakoso agba ileeṣẹ Adron Homes fi ki Ọjaja keji, o ni ọba alaye naa ti mu itẹsiwaju lọna igbalode ba aṣa ati iṣe iran ilẹ Yoruba.
O ni latigba ti Ọba Ogunwusi ti de ori apere Oduwuwa, ni Ọọni ti n lo ipo rẹ lati mu igbelarugẹ ba ipo ọba, ijidide idanimọ aṣa Yoruba ati irolagbara ipo Ile-Ifẹ nipa ti ẹmi ati iṣẹda iran Yoruba lapapọ.
Siwaju sii ni alẹnulọrọ lẹka eto ile kikọ nilẹ Naijiria naa sọ ọ di mimọ pe ọba alaye naa ti lo ipo rẹ lati fi mu itẹsiwaju ba ironilagbara awọn ọdọ, igbelarugẹ aṣa iṣẹmbaye, igbeleke imọ-ẹrọ ati idagbasoke agbegbe, to si tun n mu ki ifẹ ati alaafia jọba laaarin awọn ọmọ Afrika ati awọn Afrika to wa loke okun.
Siwaju sii lo gbadura fun Ọọni lati pẹ lori itẹ ninu ọgbọn, imọ ati oye ti ko wọpọ.
No comments:
Post a Comment