Gomina AbdulRazaq sọ anfaani meji t'awọn agbesunmọmi, ajinigbe ni, ni Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, December 28, 2025

Gomina AbdulRazaq sọ anfaani meji t'awọn agbesunmọmi, ajinigbe ni, ni Kwara


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq tipinlẹ Kwara ti sọ pe opin ti de ba gbogbo awọn agbebọn, agbesunmọmi aṣekupani kaakiri ipinlẹ naa, nitori pe ikoko ko nii gba omi, ko tun gba ẹyin mọ.
AbdulRazaq sọ pe ipinlẹ Kwara lasiko yii, kii ṣe ibugbe tabi buba fun gbogbo awọn ọdaran to n da alaafia ati ifọkanbalẹ araalu laamu.

L’opin ọsẹ to kọja yii ni awọn aṣọgbo tuntun ti ijọba ipinlẹ Kwara gba pari eto idanilẹkọọ nipa iṣẹ eto aabo, lati gbogun ti awọn agbebọn, aṣekupani ati ajinigbe ti wọn n da ilẹ naa laamu.

Nibẹ ni wọn ti pin gbogbo wọn si agbegbe ti wọn yoo ti ṣiṣẹ lati rii daju pe alaafia pada gbajọba lawọn igbo to wa kaakiri ipinlẹ naa.

Bakan naa ni gomina tun sọ pe opin ti de ba gbogbo to n jaye familete-ki-n-tutọ nipa wiwa kusa lọna aitọ, nitori pe ẹnikẹni tabi ẹgbẹkẹgbẹ tọwọ palaba wọn ba segi yoo ti ika abamọ bọ ẹnu.

O ni igbesẹ ti awọn gbe yii, anfaani meji ni yoo ṣi silẹ fawọn ajinigbe ati agbebọn aṣekupani ti a mọ si bandiiti, lara rẹ ni fifi ipinlẹ naa silẹ loju ẹsẹ, tabi ki wọn kabamọ iwa buruku wọn nipa sisan gbese ti wọn jẹ.

Siwaju sii ni asiko ree lati daabo bo gbogbo inu igbo kijikiji to wa nipinlẹ naa, eyi ti awọn oniṣẹ ibi n lo lati sapapmọ si ṣọṣẹ, ati irolagbara eto aabo araalu.

Nibẹ ni gomina ti gbe oṣuba kare fun gbogbo awọn oṣiṣẹ eleto aabo kaakiri to wa nipinlẹ naa, lai yọ eyikeyi sẹyin lori ipa ti wọn n ko lori eto aabo.

Bẹẹ lo sọ pe gbogbo ileeṣẹ eleto aabo ni wọn gbọdọ fọwọsowọpọ gidigidi lasiko yii lati rii pe wọn pawọpọ gbogun ti awọn ọdaran, paapaa ajinigbe ati agbesunmọmi. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI