Alaṣẹ Adron Homes ṣapejuwe Akarigbo ilẹ Rẹmọ gẹgẹ bi adari to kun fun ọgbọn ti ko wọpọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, December 9, 2025

Alaṣẹ Adron Homes ṣapejuwe Akarigbo ilẹ Rẹmọ gẹgẹ bi adari to kun fun ọgbọn ti ko wọpọ


Aare Adetola Emmanuelking ba Akarigbo ilẹ Rẹmọ yọ fun ti ayẹyẹ ọdun mẹtalelọgọta loke eepẹ.

Ninu atẹjade ti Aarẹ EmmanuelKing to jẹ alakoso ati oludasilẹ ileeṣẹ Adron Homes fi ki Ọba Babatunde Adewale Ajayi lopin ọsẹ to kọja yii, o ṣapejuwe ọba naa gẹgẹ bi akikanju to n gbe ilẹ Rẹmọ larugẹ kaakiri agbaye.

O ni aṣiwaju to ṣee fọkan tan ni olori ọba ilẹ Rẹmọ naa jẹ, ti ipa to n ko ninu idagbasoke igbelarugẹ aṣa ati iṣẹṣe ko ṣee fọwọ rọ sẹyin.

Aarẹ EmmanuelKing tun ṣapejuwe Akarigbo naa gẹgẹ bi adari ti igbe aye rẹ kun fun ọgbọn ti ko wọpọ, ojulowo ati oore ọfẹ alailẹgbẹ.

O ni lasiko Ọba Ajayi, ilẹ Rẹmọ ti ni oniruuru idagbasoke ati afojusun rere, eyi to n mu ki wara ati oyin ilẹ naa maa ṣe daadaa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI