Lẹyin tọwọ tẹ dokita, afurasi ajinigbe-agbesunmọmi miran tun ha ni Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, December 8, 2025

Lẹyin tọwọ tẹ dokita, afurasi ajinigbe-agbesunmọmi miran tun ha ni Kwara


Aṣeyọri tuntun ni ileeṣẹ ọlọpaa tun ti ṣe bayii, pẹlu bi ọwọ ọlọpaa tun ti ṣe tẹ awọn afurasi ajinigbe agbesunmọmi aṣekupani ti wọn n da ipinlẹ Kwara ati agbegbe rẹ laamu.

Bi ẹ ko ba gbagbe, lọsẹ to kọja yii ni ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe awọn rọwọ to awọn agbesunmọmi kan ti wọn n ko ohun ija oloro lọ fawọn ajinigbe. Opopona Gbugbu si Patigi lọwọ ti tẹ wọn.

Lẹyin eyi lọwọ tun tẹ Aliu Abubakar, afurasi ajinigbe ni papakọ Oro-Ago, ko to di pe ọwọ tẹ dokita kan ti wọn loun n ko oogun lọ fawọn agbesunmọmi ti wọn ba farapa loju ogun.

Nigba ti wọn ri Aliu, ti wọn si beere ọrọ lọwọ ẹ, wọn lo sọ pe ọdọ ẹgbọn oun loun n lọ, ṣugbọn ti irisi rẹ mu ifura dani, eyi to jẹ ki wọn ṣe iwadii rẹ, ti wọn si rii pe ọkan lara awọna afurasi ajinigbe ti wọn n wa tipẹ ni.

Iwadii ti awọn ọlọpaa ṣe pada fidi rẹ mulẹ pe ogbologbo afurasi ajinigbe ati agbesunmọmi ni  Aliu.

Wọn rii ninu fọnran nibi to ti n fi ibọn Ak-47 ṣere pẹlu awọn akẹgbẹ rẹ bii Buba, Auta ati Bello ti wọn tun n pe ni ‘Smally’.

Bakan naa ni wọn tun ri fọnran ibi to ti n fi ọpọlọwọ owo ti wọn gba nidi iṣẹ ajinigbe ṣere.

Iwadii ṣi n lọ lọwọ, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI