Oriire nla lo tun wọle tọ ipinlẹ Kwara bayii, pẹlu bi awọn akẹkọọ wọn tun ṣe gba aami ẹyẹ alailẹgbẹ wa fun wọn, to si mu ki gbogbo araalu maa fo f'ayọ.
Itan ati orukọ tuntun ni awọn akẹkọọ naa fi balẹ, ti wọn si tun gba pẹlu bi wọn ṣe peregede ninu idije ti wọn ti kopa laipẹ yii lorileede Malaysia.
Ikọ Team Kwara ni wọn pe awọn akẹkọọ naa to ṣoju ilẹ Naijiria lorileede Malaysia nibi idije ifigagbaga ti wọn pe ni 2025 Asia Parliamentary International Debate Competition (Junior Secondary School Category).
Orileede mejidinlogun kaakiri agbaye lati Aṣia, Afrika ati Yuroopu nibi ifigagbaga ọhun.
Nigba to n fi idunnu rẹ han, Gomina AbdulRahman AbdulRazaq tipinlẹ Kwara sọ pe iwuri ati idunnu nla lo jẹ foun lati gbọ iroyin ayọ naa, to si ni ipinlẹ naa ti n gun oke agba.
"Idunnu nla lo jẹ fun mi lati gbọ nipa aṣeyọri to tun gbe orukọ ilẹ Naijiria leke lori tabili agbaye ti eto ẹkọ ati ẹkọ ọfẹ. Mo gbe oriyin fun awọn akọni wa lori akitiyan wọn, imọ wọn ati ifarajin wọn. Wọn ti mu ọwọ ati okiki wa fun ipinlẹ Kwara ati Naijiria lapapọ, ti a si dupẹ lọwọ wọn.
Bakan naa ni gomina tun gbe oṣuba kare fun Ọjọgbọn Sheun Raheem Adaramaja to jẹ alakoso ajọ SUBEB, ẹni to lo jẹ igi lẹyin ọgba fun ayipada to de ba eto ẹkọ nipinlẹ naa



No comments:
Post a Comment