Oju ọna Gbugbu si Patigi ni ọwọ ti tẹ awọn afurasi naa, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.
Nnkan bi agogo meje aabọ owurọ ọjọ Ẹti to kọja yii la gbọ pe ọwọ ọlọpaa ẹkun Lafiaji to wa nijọba ibilẹ Edu tẹ awọn afurasi ọhun.
Ibọn AK-47 to gba ọgọrun kan ọta ibọn ni wọn gba lọwọ wọn lasiko ti ọwọ palaba wọn tu sepo.
Ọkọ ayọkẹlẹ Toyota Corolla ti nọmba idanimọ rẹ jẹ EP 434 ABC ni wọn fi n ko awọn ohun ija oloro naa lọ, ko to di pe ọwọ palaba wọn segi.
Yatọ si awọn nnkan ija oloro naa, oniruuru oogun abẹnugọngọ ti wọn fi n dira, la gbọ pe wọn tun gba lọwọ wọn.
Owolaramfe Rafiu to wa ọkọ ayọkẹlẹ naa, lọwọ tẹ pẹlu awọn mẹta miran; Musa Mohammed, Adam Alhaji Lawal, ati Musa Shaibu.
No comments:
Post a Comment