Ayajọ Remo: Aarẹ EmmanuelKing ba Akarigbo yọ, o tun ṣeleri iranlọwọ igbelarugẹ aṣa Remo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, December 28, 2025

Ayajọ Remo: Aarẹ EmmanuelKing ba Akarigbo yọ, o tun ṣeleri iranlọwọ igbelarugẹ aṣa Remo


Lọjọ Abamẹta to kọja yii ni gbogbo ọmọ ilẹ Remo jakejade agbaye korajọ lati ṣajọyọ ọdun wọn.

Aafin Akarigbo tilẹ Remo to wa niluu Ṣagamu, ipinlẹ Ogun ni eto ayẹyẹ naa ti waye, nibi ti gbogbo awọn alẹnulọrọ ati ọmọ bibi ilẹ Remo ti peju lati ṣahọyọ naa.

Lara awọn ti ko gbẹyin nibẹ ni Aarẹ Adetola EmmanuelKing to jẹ alakoso agba ati oludasilẹ ileeṣẹ Adron Homes to n ta ilẹ ati dukia kaakiri Naijiria.

Gbogbo ojulowo ọmọ patapata ni wọn ba ọba wọn, Akarigbo tilẹ Remo, Ọba Babatunde Adewale Ajayi yọ lori ayẹyẹ ọjọ naa ti wọn pe ni Remo Day 2025.

Gomina Dapo Abiodun tipinlẹ Ogun ati Sẹnetọ to n ṣoju ẹkun Ila-Oorun ipinlẹ naa, Ọtunba Gbenga Daniel naa ko gbẹyin.

Nigba to n sọrọ, to si fi idunnu rẹ han, Aarẹ EmmanuelKing to tun jẹ Ọtun Akilẹ Remo gbe oriyin fun Ọba Ajayi lori ipa ribiribi to n ko lẹka eto idagbasoke ati itẹsiwaju ilẹ Remo lapapọ.

Ayẹyẹ ẹlẹẹkeji iru rẹ naa ni Aarẹ EmmanuelKing ti ṣapejuwe Ọba Ajayi gẹgẹ bi ẹni to mu idagbasoke ba iṣọkan ati ohun ajogunba ilẹ Remo.

O ni eto ayẹyẹ ọdun keji lo waye lara otọ, leyi to fidi rẹ mulẹ pe awọn n gun oke agba lojoojumọ ninu igbelarugẹ aṣa ati iṣẹṣe.

Aarẹ EmmanuelKing wa ṣeleri pe ni gbogbo igba loun yoo maa ṣe iranwọ to ba yẹ lati rii daju pe eto naa ko parun titi ayeraye.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI