Ileeṣẹ ọlọpaa ilẹ Naijiria ti sọ pe ọwọ awọn ti tẹ ogbologbo agbesunmọmi aṣekupani meji ti wọn wa nidi ikọlu to n waye nipinlẹ Kwara.
Ọlọpaa sọ pe kaakiri ipinlẹ Katsina, Zamfara, Niger ati Kwara ni awọn ogbologbo bandiiti meji naa ti n ṣọṣẹ, ko to di pe ọwọ palaba wọn segi.
Ninu atẹjade ti agbẹnusọ ọlọpaa Naijiria, Benjamin Hundeyin fi sita, o sọ pe aṣeyọri nla ni awọn ṣe lọjọ Ẹti, Furaide to kọja yii.
O ni awọn kan lo ta ẹka ileeṣẹ wọn ti FID–IRT to wa nipinlẹ Kwara lolobo, ti wọn si dide lati ṣe iwadii loju ẹsẹ, leyi ti ọwọ tẹ awọn meji ọhun.
Hundeyin sọ pe agbegbe abule Komen si Masallaci to wa nijọba ibilẹ Kaiama ni ọwọ ti tẹ awọn mejeeji naa: Abubakar Usman ti inagijẹ rẹ n jẹ Siddi, ẹni ọdun mẹrindlọgbọn ati Shehu Mohammadu, ti wọn tun n pe ni Gide, ọmọ ọgbọn ọdun.
“Lasiko tọwọ tẹ wọn, a gba ọkada tuntun ‘Honda Ace 125’, eyi ti iwadii fi han pe owo ijinigbe ni wọn fi ra lọwọ wọn,” Hundeyin sọ bẹẹ.
Bakan naa lo tun jẹ ko di mimọ pe awọn gba idaji miliọnu kan naira, ibọn AK-47 to kun fun ọta ibọn ọgọfa lọwọ wọn.
Siwaju sii lo ni iwadii ti awọn ṣe nipa wọn fidi rẹ mulẹ pe yatọ si pe wọn wa lara ogbologbo bandiiti to n ṣọṣẹ kaakiri Zamfara, Katsina, Niger ati Kwara, wọn tun n ta ibọn ati ọta ibọn fawọn agbebọn bii ti wọn kaakiri Naijiria.
Bẹẹ lo ni ọga awọn, Kayọde Ẹgbẹtokun ti fi ara jin lati gbogun ti awọn agbebọn aṣekupani to n ji awọn eeyan gbe gb’owo kaakiri Naijiria.

No comments:
Post a Comment