Awọn olujọsin ti ko din ni mẹta ni ara san pa ninu ṣọọṣi, lasiko ti wọn n fi adura jagun lọwọ.
Agbegbe Senwabarwana to wa niluu Limpopo, orileede South Africa niṣẹlẹ abami naa ti waye gẹgẹ bi a ṣe gbọ.
Aarọ ọjọ Aiku to kọja yii la gbọ pe ara abami naa san, to si wọnu ijọ naa lọ, iyẹn ni abule Radimama.
Yatọ si awọn mẹta to kagbako iku ojiji naa, awọn marun-un miran la tun gbọ pe wọn farapa yannayanna, ti wọn si ti wa nile iwosan, nibi ti wọn ti n gba itọju.
Agbẹnusọ ọlọpaa, Col Malesela Ledwaba to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, jẹ ko di mimọ pe awọn mẹjọ ti ọjọ ori wọn wa laaarin ọdun mejila si mẹrindinlọgọta ni wọn fara kaaṣa.
Abule kan ti wọn n pe ni Sefihlampyana ni wọn sọ pe gbogbo awọn tọrọ kan naa n gbe.
No comments:
Post a Comment