O pari! Wọn gun Aafa to n pe irun lọbẹ pa ninu mọṣalaṣi - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, December 16, 2025

O pari! Wọn gun Aafa to n pe irun lọbẹ pa ninu mọṣalaṣi


Iyalẹnu nla gba a lọrọ aafa kan ti wọn gun lọbẹ lọrun pa nipinlẹ Kano ṣi n jẹ fawọn eeyan kaakiri agbaye.

Ilu kan ti wọn n pe ni  Hotoro Maraba, nijọba ibilẹ Tarauni, ipinlẹ Kano niṣẹlẹ abami naa ti waye lọjọ Aje, ọsẹ yii, ọjọ kẹẹdogun, oṣu Kejila, ọdun 2025.

Asiko ti aafa naa fẹẹ pe irun aarọ ni wọn sọ pe ọkunrin kan sare wọnu mọṣalaṣi, to si gun aafa naa lọrun pa.

Malam Kasim ni wọn pe orukọ aafa naa, ẹni ti wọn lo gbajumọ daadaa lagbegbe naa, nibi ti wọn lo ti fẹ pe irun naa ti wọn n pe ni Asuba lo ti pade iku ojiji.

A gbọ pe niṣẹ ni amookunṣeka naa ge ikọfun rẹ ja, titi to fi ku, tiyẹn si na papa bora.

Pẹlu ibẹrubojo ni wọn lawọn to wa ninu mọṣalaṣi naa fi juba ehoro, nigba tọrọ di bi o ko le lọ, ki o yago lọna.

Nibi ti wọn sọ pe oniṣẹ ibi naa ti n salọ, ni wọn lawọn eeyan ti sare tẹle, ti wọn si lu oun naa pa loju ẹsẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI