Gomina AbdulRahman AbdulRazaq tipinlẹ Kwara ti sọ pe ko si ẹgbẹ oṣelu miran to dara lati fi bori eto idibo nilẹ Naijiria kọja All Progressives Congress, APC.
Ojo Aiku tii ṣe Sannde to kọja yii ni Gomina AbdulRazaq sọrọ naa nibi ipade ijiroro awọn ọdọ ẹgbẹ naa ṣagbekalẹ rẹ.
Nigba to n fi atunto eto ọrọ aje ti iṣakoso Aarẹ Bola Ahmed Tinubu ṣagbekalẹ rẹ ṣe apẹẹrẹ, AbdulRazaq ni ko sohun to dara to ẹgbẹ naa.
Gomina naa jẹ ko di mimọ pe awọn alakoso ijọba ipinlẹ ti APC n ṣakoso rẹ kaakiri ilẹ Naijiria ni wọn ti ko ipa to jọju ninu aye araalu, nipa okoowo si awọn ẹka to ṣe pataki, to si ni eyi ni yoo jẹ ki ẹgbẹ naa jawe olubori ninu eto idibo ọdun 2027.
“Pataki ero rẹpẹtẹ ti awọn ọdọ ẹgbẹ oṣelu APC yii ni lati ṣafihan ati lati mọ riri awọn aṣeyọri iṣakoso APC nipinlẹ ati ni ijọba apapọ. Mo si le fi gbogbo ẹnu sọ pe ijọba APC ti ṣe daadaa to kọja afẹnusọ,” AbdulRazaq sọ bẹẹ niluu Ilorin.
“Ẹgbẹ naa ti dokoowo si awọn ẹka to ṣe pataki, ati pe naa jẹ ẹgbẹ oṣelu oan ṣoṣo to dara lati fi jawe olubori ninu eto idibo.”
Alaaji Sa'adu Salau to jẹ oludamọran pataki agba fun gomina, ẹni to ṣoju gomina nibi eto ọhun lo ṣalaye fawọn eeyan.
Akanṣe eto naa ti wọn pe ni, “Kwara APC Youth Dialogue 2025", ni apapọ ẹgbẹ awọn alatilẹyin, iyẹn Kwara Coalition of APC Support Groups ṣagbatẹru rẹ.
No comments:
Post a Comment