Ko din ni awọn olujọsin mẹtala ti wọn lawọn agbebọn aṣekupani tun ti jigbe bayii nipinlẹ Kogi, lasiko ti wọn n jọsin lọwọ ninu ijọ.
Inu ijọ igbaani, First Evangelical Church Winning All (ECWA) to wa lagbegbe Ayetoro Kiri, ijọba ibilẹ Kabba/Bunu nipinlẹ Kogi ni ikọlu ọhun ti waye lọjọ Aiku tii ṣe Sannde to kọja yii.
A gbọ pe b'awọn bandiiti naa, gẹgẹ bi wọn ṣe maa n pe wọn ṣe ji awọn eeyan naa gbe, lawọn ọlọdẹ to wa nitosi ti ba wọn fija pẹẹta pẹlu ibọn.
Mẹrin ninu awọn agbebọn naa la gbọ pe wọn pada iku ojiji lasiko ikọlu ọhun.
Kingsley Fanwo, to jẹ Kọmiṣanna feto ikansira-ẹni nipinlẹ naa fidi ikọlu naa mulẹ fawọn akọroyin lọjọ Aje ana, to si ṣapejuwe agbegbe ti ikọlu naa ti waye, gẹgẹ bi ibi ti wọn si n da oko, ṣugbọn ti iwa ipa ikọlu ti n gbooro.
O wa fọkan awọn araalu balẹ wi pe wọn yoo gba gbogbo awọn ti wọn jigbe naa silẹ, nitori pe awọn ọlọdẹ, to fi mọ awọn oṣiṣẹ eleto aabo ti wọnu igbo lati wa wọn.
“Awọn mẹtala ni wọn jigbe lasiko ikọlu naa, ṣugbọn awọn ọlọdẹ ati awọn eleto aabo miran ti bẹrẹ iṣẹ iwadii lati wa wọn ninu igbo ti wọn wọ lọ, igbesẹ naa si ni lati gba awọn ti wọn jigbe pada,” Fanwo sọ bẹẹ.
“A ni ireti to da wa loju pe gbogbo awọn ti wọn jigbe ni yoo gba itusilẹ laipẹ.”
Ikọ ologun lati ẹkun 12 Brigade, awọn ọlọpaa ipinlẹ naa, ati awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ni wọn ti bẹrẹ iṣẹ iwadii loju ẹsẹ, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.

No comments:
Post a Comment