Fun awọn to ba fẹẹ dokoowo tabi iṣẹ silẹ, ijọba Kwara ṣagbekalẹ ọna irọrun lati pa owo gidi lọdun 2026 - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, December 17, 2025

Fun awọn to ba fẹẹ dokoowo tabi iṣẹ silẹ, ijọba Kwara ṣagbekalẹ ọna irọrun lati pa owo gidi lọdun 2026


Ijọba ipinlẹ Kwara ti ṣe afihan eto igbalode tuntun fun ọdun 2026, eyi ti yoo jẹ ki awọn olokoowo tun ati tẹle ṣe okoowo wọn lọna irọrun, ti yoo tun jẹ ki wọn pa owo gidi sapo.

Agbekalẹ naa ti wọn pe ni "Ease of Doing Business in 2026", ni yoo mu imugbooro ba eto ọrọ aje, ṣiṣe okoowo ati igbayegbadun araalu.

Eto naa yoo tun gbajumọ awọn opo atunto to fi mọ lilo ilẹ lọna igbalode, idokoowo ninu iṣẹ agbẹ fun eto aabo lori ounjẹ, riro eto PPP lagbara, to fi mọ awọn miran.

Nigba to n sọrọ nibi ipade awọn alẹnulọrọ lori eto ṣiṣe okoowo lọna irọrun, Kọmiṣanna feto iṣuna, ẹni to tun jẹ alaga igbimọ eto ṣiṣe okoowo lọna irọrun nipinlẹ Kwara, Ọmọwe Hauwa Nuru ṣalaye awọn ifarajin ijọba lori iṣakoso to n jẹ ki araalu mọ bo ṣe n lọ, ati jijẹ ki awọn alẹnulọrọ ni ipa ti wọn n ko.

Gẹgẹ bo ṣe ṣalaye, o ni agbekalẹ ijọba ni lati tẹsiwaju, ko le mu ayipada rere ba agbegbe okoowo, nipa titẹ awọn eeyan, paapaa onibara lọrun, labẹ eto to pe ni SABER.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI