...O tun ko awọn ọmọ ẹyin rẹ dani
Oludije sipo igbakeji alaga ijọba ibilẹ Offa labẹ asia ẹgbẹ oṣelu People's Democratic Party, PDP, Ọnarebu Adedoyin Adesoye lo ti kọwe fi ẹgbẹ naa silẹ.
Ọnarebu Adesoye sọ pe oun ko le tẹsiwaju ninu ẹgbẹ naa mọ, nitori awọn kudiẹkudiẹ to n ṣẹlẹ, eyi ti awọn agbaagba ẹgbẹ ko le ṣabojuto ẹ.
Ko si nnkan to n jẹ ki ọrọ Adesoye, ẹni to tun jẹ Ọmọọbabinrin maa ya awọn eeyan lẹnu, bi ko ṣe pe gbogbo awọn ọmọ ẹyin ati alatilẹyin rẹ nidi oṣelu lo ko kuro ninu ẹgbẹ naa.
Ninu lẹta ti obinrin naa kọ ranṣẹ si alaga ijọba oṣelu PDP ni wọọdu Essa ‘C’, Ọnarebu Adesoye sọ pe, oun gbe igbesẹ naa nitori awọn eeyan to n tẹle oun, ati pe iwe toun kọ fidi mulẹ loju ẹsẹ.
“Emi, Ọmọọbabinrin Adedoyin Adesoye, oludije sipo igbakeji alaga ijọba ibilẹ Offa ninu eto idibo ijọba ibilẹ to waye lọdun 2023 kọ iwe yii lati jẹ ko di mimọ pe nko ṣe ẹgbẹ PDP mọ, lati wakati yii lọ,” lẹta naa ka bẹẹ.
Adesoye, lo dije labẹ tikẹẹti kan naa pẹlu Ọnarebu Salahudeen Lukman, ti ọpọ eeyan mọ si Ọmọ Adugbo.
Ọmọọbabinrin naa fi imọriri rẹ han si awọn alakoso ẹgbẹ fun anfaani to ri gba lati jẹ ọmọ ẹgbẹ naa, titi toun fi di oludije ninu idibo ijọba ibilẹ to waye kọja.
Latigba to ti kede yii, ni ọrọ rẹ ti di ohun ti awọn eeyan n sọ nigboro, nitori iyalẹnu ni wọn lo jẹ fun ọpọ eeyan.
No comments:
Post a Comment