Ninu atẹjade ti alakoso eto ikansira-ẹni fun ileeṣẹ National Counter Terrorism Centre, Ọgbẹni Abu Michael, fi sita, o sọ pe awọn gbe igbesẹ naa labẹ ofin ilẹ Naijiria, lati gbogun ti awọn agbesunmọmi.
Ipin kẹta ni abala kẹrin, ikarun ati ikẹfa ti aabo fun iwa igbesunmọmi, iyẹn Terrorism Prevention and Prohibition Act) ti ọdun 2022, ajọ National Counter Terrorism Centre (NCTC), to wa labẹ akoso ONSA, sọ pe awọn n ṣe iranwọ lati gbogun ti iwa awọn agbesunmọmi aṣekupani kaakiri Naijiria.
Michael sọrọ yii lati fi tako awọn oniruuru iroyin to n fo kaakiri ipinlẹ Kwara nibi ti wọn ti sọ pe wọn ri ibọn ti ileeṣẹ NSA fi sita gba pada nipinlẹ naa.
O wa rọ awọn oniroyin lati maa ṣe iwadii daadaa, ki wọn si maa daabo bo awọn iroyin to ba yẹ, ati pe ki wọn maa gba itọni tabi beere ibeere to tọ lati ọdọ awọn agbẹnusọ.
Gẹgẹ bo ṣe sọ siwaju, o ni oniruuru iwe ori ayelujara ni wọn ti gbe iroyin nipa ohun to ṣẹlẹ, to si di dandan fun wọn lati jẹ ki gbogbo eeyan mọ otitọ to wa nibẹ, paapaa lori awọn nnkan to n ṣẹlẹ ni Kwara.
No comments:
Post a Comment