Igbayegbadun araalu ati oṣiṣẹ lo jẹ wa logun ninu bọjẹẹti ọdun 2026 - Gomina AbudlRazaq - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, December 23, 2025

Igbayegbadun araalu ati oṣiṣẹ lo jẹ wa logun ninu bọjẹẹti ọdun 2026 - Gomina AbudlRazaq


Lọjọ Aje ọsẹ yii ni Gomina 
AbdulRahman AbdulRazaq aba gbe eto iṣuna ọdun 2026 lọ sile igbimọ aṣofin lati buwọ lu, fun itẹsiwaju ipinlẹ ipinlẹ Kwara.

Gbogbo awọn aṣofin ipinlẹ Kwara, to fi mọ awọn ọba alaye, ati awọn alẹnulọrọ kaakiri ipinlẹ naa ni wọn wa nibi eto ọhun to waye ninu gbọngan ile igbimọ aṣofin to wa niluu Ilorin.

Bi awọn akanṣe to n lọ lọwọ yoo ṣe tete pari, ọrọ eto aabo, igbayegbadun awọn araalu, paapaa awọn oṣiṣẹ ijọba, eto ẹkọ, ati awọn nnkan miran ni gomina mu lọkunkundun ninu bọjẹẹti tuntun naa.

Ida mẹrindinlaadọrin din ni marun-un ni yoo jẹ fun awọn iṣẹ akanṣe gboogi, nigba ti eyi to ku yoo lọ fun awọn eto to ti wa nilẹ tẹlẹ fun igbayegbadun, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.

"Pẹlu ogo fun Ọlọrun fun aanu ati itọni rẹ, lẹẹkansii mo gbe aba eto iṣuna ọdun 2026 wa siwaju ẹyin igbimọ aṣofin, ni ibamu pẹlu abala kọkanlelọgọfa, ipin kinni to wa ninu iwe ofin ilẹ Naijiria," Gomina sọ bẹẹ. 

"Apapọ gbogbo owo ti a fẹẹ na lo le ni ẹgbẹta biliọnu naira, iyẹn N644,004,816,893.00.

"Agbekalẹ yii lo n tọ wa sọna lọ ninu ọdun tuntun. A maa gbajumọ bi a ṣe maa pari awọn akanṣe iṣẹ to ti n lọ tẹlẹ, ti a si tun maa ṣiṣẹ ni awọn ẹka to nilo pajawiri bii irinṣẹ eto aabo to nii ṣe pẹlu ọkọ ati awọn irinṣẹ igbalode lati le rii daju pe a gbogun ti iwa awọn ajinigbe ati iwa buruku miran.

"Awọn akanṣe iṣẹ miran la tun n gba lero lati gba wọle, ki a le mu Kwara pada bọ sipo."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI