Wolii Ayọdele sọ awọn ohun ti yoo ṣẹlẹ lọdun 2026, adura gidi ni Naijiria nilo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, December 23, 2025

Wolii Ayọdele sọ awọn ohun ti yoo ṣẹlẹ lọdun 2026, adura gidi ni Naijiria nilo


Lopin ọsẹ to kọja yii ni Wolii Babatunde Elijah Ayọdele to jẹ alaṣẹ ati oludasilẹ ijọ INRI Evangelical Spiritual to wa nipinlẹ Eko, sọ aṣotẹlẹ awọn ohun ti yoo ṣẹlẹ lọdun 2026 ati awọn ọdun ti yoo tẹlẹ.

Nibẹ lo ti mẹnuba ọrọ eto oṣelu ọdun 2027, to si ṣe ikilọ nla fun Aarẹ Bọla Ahmẹd Tinubu lati ṣọra fun pupọ ninu awọn ọmọ ẹyin rẹ nitori pe wọn yoo gbabọde fun un.

Agba Wolii sọ pe aarẹ  ni lati ṣọra fun awọn fun ọpọ awọn oloṣelu, paapaa awọn agbaagba oloṣelu nilẹ Hausa, nitori pe wọn yoo ṣiṣẹ tako o, ti wọn ko si ni fẹ ko pada sipo naa lẹẹkeji.

“Awọn agbaagba ilẹ Hausa kan yoo ṣiṣẹ tako Tinubu,” Wolii Ayọdele sọ bẹẹ ninu asọtẹlẹ tuntun rẹ.

Eto asọtẹlẹ yii kii ṣe akọkọ ti Wolii Ayọdele yoo maa gbe kalẹ, ti pupọ ninu awọn asọtẹlẹ rẹ si ti wa si imuṣẹ lọpọ igba.

Siwaju sii ni ogbontarigi wolii naa sọ pe ẹgbẹ oṣelu nla mejeeji to n lewaju yoo ṣe magomago ninu eto idibo ọdun 2027, ati pe bi wọn ba ṣe n fi owo ra ibo, naa ni wọn yoo tun ji ibo gbe.

“Ẹgbẹ oṣelu nla meji to n lewaju yoo yi ibo, bẹẹ ni wọn yoo tun ra ibo, ti wọn yoo si tun ji ibo gbe. Tinubu nilo lati ṣiṣẹ lẹkun Aarin gbungbun Ariwa ati Guusu Ila-Oorun. Awọn ọmọ ẹyin Tinubu kan yoo ṣiṣẹ fun awọn alatako.

“Awọn ẹgbẹ alatako yoo gbe ibanilorukọjẹ ati iroyin ẹlẹjẹ jade nipa Tinubu. Ọpọ awọn agbaagba ti Tinubu gbẹkẹle yoo dalẹ rẹ. Ẹkun Ariwa yoo pin si meji nitori Tinubu. Mo ri awọn alamin ninu ẹgbẹ oṣelu alatako.

“Mo ri iyapa ati iwa ọdalẹ ninu eto aabo ilẹ Naijiria. Bi Tinubu ba ṣe n gbiyanju lati da awọn ẹkun Ariwa lare, bẹẹ naa lawọn eeyan yoo ṣe maa ṣiṣẹ takoo. Awọn alẹnulọrọ ẹkun Ariwa yoo tan Tinubu jẹ.

“Tinubu yoo ṣiṣẹ takuntakun ninu ẹmi, ninu eto iṣuna ati ọgbọn lati yege ninu eto idibo ọdun 2027. Tinubu ni lati tete gbe igbesẹ to ba fẹẹ jawe olubori. Eto idibo ko nii tete waye.”

Yatọ si eyi, Wolii Ayọdele tun mẹnuba ọrọ eto aabo, ile ifowopamọ, ere idaraya ati orileede miran, to si ni; “Apo aṣuwọn yoo da wahala silẹ fawọn ile ifowopamọ kan.

“Wọn yoo kọlu awọn gomina, sẹnetọ ati minisita. Ẹ jẹ ki awọn ṣọọṣi, mọṣalaṣi daabo bo ile ijọsin wọn daadaa. Ajọ EFCC yoo tu aṣiri ọpọ awọn oloṣelu.

“Atiku ni lati gbaradi nitori pe wọn ti n palẹmọ lati gbe iroyin atako jade nipa rẹ. Ilẹ Naijiria yoo ri owo tabua ninu eto irin ajo afẹ, bẹẹ si ni wọn yoo ni idagbasoke ninu eto aabo ori ayelujara.

“Tinubu ati Dangote yoo ja. Ẹ jẹ ka gbadura ki a ma ba a padanu awọn gbajumọ sinu ijamba ọkọ ofurufu. Ilẹ Naijiria yoo padanu abẹṣẹkubiojo ati agbabọọlu kan.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI