Ijọba Kwara gba ẹgbẹrun meji aṣọgbo si iṣẹ, gomina tun gba wọn lamọran - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, December 7, 2025

Ijọba Kwara gba ẹgbẹrun meji aṣọgbo si iṣẹ, gomina tun gba wọn lamọran


Laipẹ yii ni Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ṣe abẹwo si ilẹ idanilẹkọọ awọn aṣọgbo tuntun ti ijọba Kwara fẹẹ gba si iṣẹ, to si gba wọn lamọran lati ṣiṣẹ wọn gẹgẹ bi iṣẹ.

Lojuna lati le daabo bo awọn igbo ọba kuro lọwọ awọn amookunṣeka, lo fa a ti ijọba fi gbe igbesẹ ọhun.

Ẹgbẹrun meji aabọ le diẹ (2,600) ni awọn aṣọgbo naa ti wọn yoo ṣọ igbo ọba kaakiri ipinlẹ Kwara.

Lasiko abẹwo naa, gomina gba wọn lamọran pe ki wọn mu iṣẹ naa lọkunkundun, paapaa lati le daabo bo ẹmi ati dukia araalu kaakiri ipinlẹ naa.

Ninu atẹjade ti amugbalẹgbẹ pataki fun gomina lori eto iroyin igbalode, Akewejẹ Olayinka Fafoluyi tọpọ tun mọ si Solace fi sita, o ni abẹwo gomina ni lati fun awọn oṣiṣẹ tuntun naa ni koriya, ati lati le fọkan araalu, paapaa awọn to koju iṣoro eto aabo laipẹ yii balẹ, pe alaafia yoo pada bọ, ti ifọkanbalẹ yoo si wa lawọn igberiko.

Awọn alakoso eto idanilẹkọọ naa ni wọn jẹ ko di mimọ pe gbogbo awọn eeyan tuntun yii ni wọn n fọwọsowọpọ, ati pe aridaju wa pe wọn yoo ṣe daadaa nigba ti iṣẹ ba bẹrẹ lẹkunrẹrẹ.

"Gbogbo eto ni iṣakoso Gomina AbdulRazaq n fi si ojuṣe lati rii pe alaafia jọba, ti ko si si wahala kankan mọ. Awọn aṣọgbo to le ni ẹẹdẹgbẹrin ni ijọba ti gba, ti wọn si ti ṣe idanilẹkọọ ologun fun wọn ti wọn si tun ti n ṣiṣẹ pẹlu awọn oṣiṣẹ eleto aabo yooku lati gbogun ti iṣoro to n koju eto aabo," Fafoluyi sọ bẹẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI