Orin "ija d'opin, ogun si tan..." ni awọn gbajumọ oṣere tiata nni, Afeez Ọwọ Abiọdun ati Wumi Toriọla n kọ bayii, nigba ti wọn yanju aawọ to wa laarin wọn.
Wumi Toriọla lo lọ ba Afeez Ọwọ loko ere, to si loun ti ri aṣiṣe oun, ati pe oun ko tun jẹ ṣe bẹẹ mọ.
Ninu ọrọ to kọ soju opo ayelujara ti Facebook rẹ, Wumi sọ pe “Mo pinnu lati bẹ agba wa, nitori ti mo jẹ aṣoju aṣa, koda nigba “ibinu”, awọn agba wa ni lati maa ṣe suuru.
Ati pe nitori awọn agba wa nilo omi tutu, kii ṣe pe ki wọn maa pariwo.


No comments:
Post a Comment