Ijọba sọ pe iroyin ẹlẹjẹ to jinna si otitọ ni, ati pe ọna lati ṣi ọpọ awọn araalu lọkan ni awọn alatako n wa.
Ninu atẹjade ti Kọmiṣanna feto iroyin nipinlẹ Kwara, Bolanle Olukoju fi sita l'Ọjọbọ to kọja yii, o ni ijọba ko gbe iṣẹ akanṣe kankan fun Mutawali tilu Ilorin, ẹni to tun jẹ ẹgbọn gomina, Ọmọwe Alimi AbdulRazaq.
Olukoju sọ pe Ọnarebu Iliasu Ibrahim lo sọ ọrọ naa sita lati da ilu ru, wi pe gomina gbe igbesẹ naa, to si lo ku diẹ kaato.
“Ko si igba kankan ti ijọba gbe iṣẹ akanṣe to to miliọnu lọna ẹgbẹrin dọla sita. A ti gbọ nipa ọrọ asọdun ti ko tọna, eyi ti Ọnarebu Iliasu Ibrahim sọ lori redio laipẹ yii wi pe gomina gbe iṣẹ akanṣe tabi pe ironilagbara kalẹ fun ẹgbọn rẹ. Iroyin ẹlẹjẹ ti ko l'ẹsẹ nilẹ rara ni, atẹjade naa sọ bẹẹ.
No comments:
Post a Comment