Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ, DSS ti tẹ oniṣegun oyinbo kan to n ko oogun lati ipinlẹ Sokoto lọ fawọn ajinigbe lawọn agbegbe kan nipinlẹ Kwara.
Ilu Jebba ni iroyin sọ pe ọwọ ti tẹ akọṣẹmọṣẹ oniṣegun oyinbo naa, lẹyin ti awọn DSS gba olobo kan, eyi to jẹ ki wọn tọpinpin dokita naa.
A gbọ pe dokita tọwọ tẹ naa lo n ṣe itọju awọn to fi ara gbọta nibi ikọlu awọn oṣiṣẹ aabo ati ajinigbe naa.
No comments:
Post a Comment