Ko sẹni to sọ fawọn olukọ lati gunle ifẹhonuhan o - Ẹgbẹ olukọ ni Kwara pariwo sita - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, December 24, 2025

Ko sẹni to sọ fawọn olukọ lati gunle ifẹhonuhan o - Ẹgbẹ olukọ ni Kwara pariwo sita


Egbe awọn olukọ nilẹ Naijiria, NUT, ẹka tipinlẹ Kwara ti fidi rẹ mulẹ pe ko sẹni to pa a laṣẹ fun awọn ọmọ ẹgbẹ wọn lati gunle ifẹhonuhan nipinlẹ naa.

Wọn lawọn ko sọ fun ẹnikẹni tabi ẹgbẹkẹgbẹ kankan lati bẹrẹ ifẹhonuhan lati takp ijọba tabi ileeṣẹ tabi ẹnikẹni nipinlẹ Kwara.

"Eyi ni lati fi to gbogbo eeyan leti pe ẹgbẹ awa olukọ, Nigeria Union of Teachers (NUT) ẹka ti Kwara ati awọn adari rẹ ko paṣẹ tabi dari awọn olukọ ile-ẹkọ ijọba nipinlẹ yii, tabi ẹnikẹni tabi ẹgbẹ, lati gunle ifẹhonuhan lodi si ileeṣẹ tabi ajọ, eeyan, tabi ijọba lori ohunkohun," atẹjade ti alaga, Yusuf Wahab Agboola ati igbakeji akọwe, MONI Mike Modesty Itua buwọ lu sọ bẹẹ.

"Lori ohun ti a sọ yii, ẹnikẹni tabi ẹgbẹ kankan to ba gunle ifẹhonuhan lati tako ijọba lori ohunkohun ti wọn ko ba a fun un lati ṣoju awọn olukọ, iru awọn eeyan bẹẹ ṣe e lọwọ ara wọn ni."

O wa sọ pe ki gbogbo awọn olukọ nipinlẹ naa ma ṣe tẹle aṣẹ ti ko kade lati ọdọ awọn olori wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI