Lẹyin ọpọlọpọ ọdun, Gomina AbdulRazaq buwọlu Muftau Bayọ gẹgẹ bi ọba Elesha tilu Oke-Ode ni Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, December 3, 2025

Lẹyin ọpọlọpọ ọdun, Gomina AbdulRazaq buwọlu Muftau Bayọ gẹgẹ bi ọba Elesha tilu Oke-Ode ni Kwara


Titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii ni inu awọn araalu Oke-Ode to wa nijọba ibilẹ Ifelodun, ipinlẹ Kwara fi n dun, ti wọn si n fo fun ayọ, pẹlu bi Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ṣe buwọlu Ọba Shaaba Muftau Bayọ gẹgẹ bii Elesha tuntun.

Ipo keji ni ọba naa yoo wa ninu agbekalẹ awọn ọba alaye nipinlẹ naa.

Ninu atẹjade ti Kọmiṣanna f'ọrọ ijọba ibilẹ ati oye jijẹ nipinlẹ naa, Ọnarebu Abdullahi Abubakar Bata fi sita, o jẹ ko di mimọ pe ilu kii wa lai ni olori, idi ree ti gomina fi yan olori tuntun fun wọn.

A gbọ pe o ti ṣe diẹ ti awọn araalu naa ti n rawọ ẹbẹ si ijoba lati buwọlu ọba tuntun fun wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI