Ṣebi ọrọ awọn agba to ronu jinlẹ pe 'Bi a ba n ja, bii ka ku kọ', lo fa bi Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ṣe ba iyawo gomina tẹlẹ ri nipinlẹ naa, Bukọla Saraki, iyẹn Arabinrin Toyin Saraki kẹdun iku baba rẹ, Oloogbe Ọtunba Adekunle Ojora to jade laye.
Gomina AbdulRazaq tun ba gbogbo idile Ojora tiluu Ekoo kẹdun lori iku ọkan pataki ninu ẹbi wọn to doloogbe.
Ninu atẹjade ibanikẹdun ti gomina fi ranṣẹ lati ọwọ akọwe iroyin rẹ, Ọgbẹni Rafiu Ajakaye, o ṣapejuwe oloogbe naa gẹgẹ bi ẹni to ti ko ipa ribiribi lawujọ fun ilọsiwaju ọmọniyan.
Gomina AbdulRazaq sọ pe iṣẹ rere ti baba naa ti ṣe silẹ ko too jade laye, yoo tu gbogbo ẹbi lara lasiko ti wọn padanu rẹ yii.
O wa gb'adura pe bi Ọlọrun ti n tu gbogbo ẹbi ninu, bẹẹ ni ko tẹ baba naa si afẹfẹ rere.
No comments:
Post a Comment