Wahala! Ile-ẹjọ fi ẹsun ọdaran kan Iliasu, gbajumọ Ọnarebu n'ilorin - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, January 9, 2026

Wahala! Ile-ẹjọ fi ẹsun ọdaran kan Iliasu, gbajumọ Ọnarebu n'ilorin


Ile-ẹjọ giga tipinlẹ Kwara, eyi to wa niluu Ilorin ti fi iwe ẹsun ọdaran ranṣẹ pe Ọnarebu Iliasu Ibrahim pẹlu bo ṣe kọ lati yọju lori ẹsun ibanilorukọ jẹ to wọn fi kan oun ati awọn meji miran.

Bo tilẹ jẹ pe awọn afurasi meji yooku, Shola Muse ati Adeso.owo Adegogo farahan niwaji ile-ẹjọ naa, ṣugbọn agbẹjọro Ọnarebu Iliasu sọ fun ile-ẹjọ l'Ọjọru, ọsẹ yii pe onibara oun wa lori idubulẹ aisan, ko si le yọju, to si ni ki ile-ẹjọ gbọ ẹbẹ rẹ.

Ohun ti a gbọ ni pe Onidajọ E . B Mohammed wa gbe iwe ipe ẹsun ọdaran dide si Iliasu, wi pe dandan ni ko yọju sile-ẹjọ logunjọ, oṣu Kinni, ọdun 2026.

Bi ẹ ko ba gbagbe, Ọnarebu Iliasu kọ lati farahan niwaju ile-ẹjọ naa lọjọ kọkandinlogun, oṣu Kejila, ọdun 2025, ti agbẹjọro rẹ si bẹbẹ pe ọkunrin naa wa lori idubulẹ aisan.

Idi ree ile-ẹjọ fi sun igbẹjọ miran si ọjọ keje, oṣu Kinni, ọdun 2026 lati le jẹ ki Iliasu farahan funra rẹ.

Ohun ti a gbọ ni pe awọn afurasi mẹtẹẹta ni wọn lọ sori redio lati fi ẹsun kan Matawali tilui Ilorin, Ọmọwe Alimi Abdulrazaq wi pe o gba akanṣe iṣẹ ti ko din ni ọgọsan miliọnu dọla {$800m).

Wọn ni aburo rẹ to jẹ gomina lo gbe iṣẹ naa fun un, ṣugbọn ti aṣiri ti pada tu pe irọ to jinna si otitọ ni.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI