Fun ọpọlọpọ ọdun ni ọrọ ile gbigbe nilẹ Naijiria ti jẹ afojusun ọpọ awọn eeyan, paapaa lati di onile lori, to si jẹ awon idojukọ rẹ ko kọja bi owo ilẹ ṣe n gbowo lori, to si je pe ko si anfaani fun eto rira ile lati maa san owo diẹ diẹ.
Ọdun mẹrinla sẹyin ni ileeṣẹ Adron Homes dide lati wa ọna abayọ ti yoo sọ ọpọ eeyan di onile lori lai daamu jinna.
Wọn tẹdo lori ilana ati afojusun wi pe ile gbigbe ati dukia nini gbọdọ jẹ ẹtọ ọmọniyan, kii ṣe anfaani, idi ree ti wọn fi n gbe oniruuru eto kalẹ fun awọn eeyan lati jẹ anfaani, ki wọn le di onile lori.
Lara awọn agbekalẹ naa ni pe ile tabi dukia ti awọn eeyan n foju sun ni wọn n ni, lai wo apo wọn, ko nii ṣe pẹlu bo ti pẹ to.
Ni bayii, ọpọ awọn lo ti jẹri sii pe ọkan pataki ni ileeṣẹ Adron Homes jẹ lati fi idunnu ati ayọ sọkan awọn eeyan lati di onile lori.
No comments:
Post a Comment