AbdulRazaq pe ipade pajawiri pẹlu awọn olori alaabo ni Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, February 10, 2026

AbdulRazaq pe ipade pajawiri pẹlu awọn olori alaabo ni Kwara


Lojuna lati dena ikọlu awọn agbebọn aṣekupani to n ṣẹlẹ nipinlẹ Kwara, Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti pe ipade pajawiri pẹlu awọn olori eleto aabo.

Ile ijọba ti Ahmadu Bello to wa niluu Ilọrin ni gomina pe awọn olori eleto aabo naa si, lati sọrọ lori ọna abayọ si ikọlu awọn agbebọn agbesunmọmi to waye nijọba ibilẹ Kaiama laipẹ yii.

Nibẹ ni Gomina ti sọ pe ẹmi ati dukia araalu jẹ iṣakoso oun logun pupọ, idi ree to fi loun n wa ọna lati daabo bo wọn.

Gomina loun nigbagbọ pe ipade awọn yoo so eso rere lati mu igbalarugẹ ba eto aabo nipinlẹ naa, ti alaafia ati ifọkanbalẹ yoo si maa jọba.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI