Ijọba ipinlẹ Kwara ti sọ pe ko si otitọ kankan ninu iroyin ẹlẹjẹ ti wọn n gbe kaakiri pe wọn kofiri Iba Lassa ni ọgba idanilẹkọọ awọn agunbanirọ nipinlẹ naa.
Ileeṣẹ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri nipinlẹ naa, Kwara State Rapid Response Team (RRT) ni wọn fidi rẹ mulẹ pe iroyin to jinna si otitọ ni wọn n gbe kaakiri ori ikanni ayelujara.
RRT sọrọ naa lẹyin ti akọṣẹmọṣẹ Oniṣegun Oyinbo Kamaldeen Khadeejah fidi rẹ mulẹ.
Ọjọ Aiku, ọjọ kẹjọ, oṣu Keji, ọdun 2026 ni iroyin naa jade sori ikanni ayelujara wi pe agunbanirọ kan ku, ti wọn si fura sii pe aisan Iba Lassa lo ṣeku pa a.
Wọn ni iwadii ijinlẹ fidi rẹ mulẹ pe ko sohun to jọ wi pe Iba Lassa wa nipinlẹ naa, depodepo wi pe yoo ṣeku pa eeyan.

No comments:
Post a Comment