Idunnu lo ṣubu lu ayọ mọlẹbi awọn agbaṣẹṣe meje kan ti awọn agbebọn jigbe laipẹ yii nipinlẹ Kwara, nigba ti wọn tu wọn silẹ ninu igbekun.
Ọjọ Aje, ọsẹ yii la gbọ pe wọn tu gbogbo awọn agbaṣẹṣe naa silẹ kuro lahaamọ.
Kọmiṣanna fọrọ iṣẹ ode, Onimọ-ẹrọ Abdulquawy Olododo lo fidi iroyin naa mulẹ lonii, ọjọ Aje, ninu atẹjade ti akọwe iroyin rẹ, Olajide Abolarin fi sita.
Bi ẹ ko ba gbagbe, ọsẹ to kọja ni iroyin naa jade pe awọn agbebọn kọlu ilu Owa Onire to wa nijọba ibilẹ Ifelodun, ti wọn si ji awọn eeyan gbe lọ nibẹ.
Nigba to n gbe oṣuba kare fun Gomina AbdulRahman AbdulRazaq lori akitiyan rẹ lati rii pe awọn agbaṣẹṣe naa gba itusilẹ, o ni ẹmi ati ati dukia jẹ ijọba ipinlẹ naa logun pupọ.
Lara awọn ti wọn jigbe naa onimọ-ẹrọ meji lati ileeṣẹ to n ri si iṣẹ ode.

No comments:
Post a Comment