Adron Homes ba awọn Musulumi yọ fun Aawẹ Ramadaani - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, February 20, 2026

Adron Homes ba awọn Musulumi yọ fun Aawẹ Ramadaani

Alaṣẹ ati alakoso agba fun ileeṣẹ Adron Homes & Properties Limited nilẹ Naijiria ti ba gbogbo awọn ẹlẹsin Musulumi yọ lori aawẹ Ramadaani to wọle de, to si n parọwa si wọn lati fi ara jin, ki wọn si ko ara wọn nijanu lasiko aawẹ yii.

Aarẹ EmmanuelKing lo sọrọ yii ninu atẹjade ti ileṣẹ rẹ fi sita lọjọ Ẹti, Furaidee, ogunjọ, oṣu Keji, ọdun 2026.

Ọga agba naa sọ pe oṣu mimọ ni oṣu aawẹ naa jẹ lati ṣe aṣaro ijinlẹ, ki wọn si tun ara wọn ṣe ninu ẹmi, bẹẹ si ni ifrajin ninu okun si igbagbọ ati iwa ọmọniyan.

“Ramadan jẹ asiko to n kọ eeyan ni suuru, ififunni ati igbagbọ ninu ara ẹni. Bi awọn onibara wa ti wọn jẹ Musulumi ati alatilẹyin wa ṣe bẹrẹ aawẹ, a gbadura pe ki adura ati irubọ wọn jẹ itẹwọgba, ati pe ki asiko yii mu alaafia, ayọ ati atunṣe ireti wa si ile wọn, ati ilẹ Naijiria lapapọ,” atẹjade naa sọ bẹẹ.

Alakoso ileeṣẹ naa wa fi ọkan awọn araalu balẹ wi pe awọn yoo tubọ maa pese ọna abayọ si iṣoro ile gbigbe, lati rii pe gbogbo eeyan di onile lori, fun ifọkanbalẹ ọjọ alẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI