Ẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress, APC nipinlẹ Kwara ti buwọ lu iyasipo awọn adari tuntun fẹgbẹ naa ni wọọdu Ipetu, Rore ati Aran-Orin.
Gbogbo awọn alẹnulọrọ patapata fun ẹgbẹ naa lawọn wọọdu wọnyi la gbọ pe wọn buwọ lu iyansipo awọn alakoso tuntun naa, fun itẹsiwaju ẹgbẹ, ati aṣeyọri ninu eto idibo to n bọ lọna.
Iyansipo naa lo waye nibi ipade gbogboogbo wọọdu naa to waye l'Ọjọru, ọsẹ yii, ọjọ kejidinlogun, oṣu Keji, ọdun 2026.
Awọn ọmọ ẹgbẹ, alatilẹyin, alẹnulọrọ, to fi mọ afẹnifẹre patapata ni wọn wa nibi ipade naa, lati fontẹ lu awọn oloye tuntun naa.
Nibẹ ni awọn alakoso tuntun naa ti fọkan gbogbo ọmọ ẹgbẹ balẹ wi pe awọn yoo mu itẹsiwaju ba ẹgbẹ naa, nipa iṣọkan, ifẹ ati kiko ero wọle.
Wọn ṣeleri lati maa ṣatilẹyin fun iṣakoso Gomina Abdulrahman Abdulrazaq ati Aarẹ Bola Ahmed Tinubu ni gbogbo igba.
Nigba to n sọrọ, amugbalẹgbẹ pataki fun Gomina lori eto aṣa ati irin-ajo afẹ, Ọnarebu Eyiwumi Aramide Muka jẹ ko di mimọ pe iyansipo-pada fun awọn alakoso tuntun naa, jẹ aridaju wi pe wọn fi ọkan wọn sin adari wọn, Gomina Abdulrahman Abdulrazaq, to si gba wọn lamọran lati ma ṣe yẹgẹrẹ.
Ninu ọrọ tiẹ naa, amugbalẹgbẹ agba pataki si gomina lori eto iroyin igbalode, Akewejẹ tiluu Aran-Orin, Oloye Olayinka Fafoluyi, pe fun iṣọkan ninu ẹgbẹ.
Akewejẹ Fafoluyi ni ohun to ṣe pataki to le mu ki ẹgbẹ ni ilọsiwaju ni ifẹ ati iṣọkan ni gbogbo igba.
Awọn alakoso tuntun naa ni:
(1) Alaga
2) ỌNAREBU JOSHUA OYINLOYE: Igbakeji alaga
3) ARABINRIN ADEOTI ADAMO DUPE: Olori awọn obinrin
4) OWOLABI KIKELOMO: Igbakeji olori awọn obinrin
5) AJAYI ALAWODE: Olori awọn ọdọ
6) BAMIKOLE JOHN: Igbakeji olori awọn ọdọ
7) ONIFADE ENIOLA REBECCA: Akọwe
8) ADEBAYO MICHEAL: Igbakeji akọwe
9) AKOLADE ROMOKE: Akapo
10) ALFA SULAIMAN HASSAN: Igbakeji Akapo
11) AJIBOYE ISMAEEL: Akọwe iṣuna
12) KUNLE ODETUNDUN: Igbakeji akọwe iṣuna
13) HABEEB OWOLABI: Akọwe ọrọ ọmọ ẹgbẹ
14)KEHINDE OLAREWAJU: Igbakeji Akọwe ọrọ ọmọ ẹgbẹ
15) ALICE BAMIDELE: Akọwe eto
16) IDOWU TAYE: Igbakeji akọwe eto
17) MOJIROLA JOLAYEMI: Alukoro
18) TAIWO ADEDIRAN: Alukoro keji
19) ABOLAJI RUKAYAT: Oluṣiro owo
20) AFOLAMI CAROLINE: Igbakeji oluṣiro owo
21) BABALOLA VICTORIA: Olugbanilamọran ofin
22) ISMAEEL OYINLOYE: Igbakeji olugbanilamọran ofin
23) ADEBAYO EMMANUEL: Alabojuto awọn akanda
24) MUSA IBRAHIM: Ex officio I
25) DELE TAIWO: Ex-officio II
26) OLABANJI AWOYEMI: Ex officio III
27) AJIBOYE DOSU: Ex Officio IV

No comments:
Post a Comment