'Operation Savannah Shield' bẹrẹ lati gbogun ti awọn agbebọn aṣekupani ni Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, February 20, 2026

'Operation Savannah Shield' bẹrẹ lati gbogun ti awọn agbebọn aṣekupani ni Kwara


L'Ọjọbọ, ọsẹ yii ni ifilọlẹ ikọ ọmọ ogun ti yoo gbogun ti awọn agbebọn aṣekupani ti wọn pe ni 'Operation Savannah Shield' waye nipinlẹ Kwara, nibi ti Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti bu ọla fun awọn ologun.

Igbesẹ yii lo jẹ ọkan lara awọn ọna lati koju iṣoro to n doju kọ eto aabo nipinlẹ Kwara.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, awọn ọmọ ogun yii ni yoo wọnu igbo lati gbogun ti gbogbo awọn ọta ipinlẹ Kwara ti wọn n kogun ja awọn araalu.

Nibi ifilọlẹ naa to waye ni baraaki ologun ti Sobi niluu Ilorin, ni Gomina AbdulRazaq ti gbe oṣuba kare fun Aarẹ Bola Ahmed Tinubu, lori bo ṣe buwọ lu agbekalẹ naa.

Olori awọn ọmọ ogun nilẹ Naijiria, Ọgagun Olufemi Olatubosun Oluyede, ati olori awọn ọmọ ogun, Ọgagun Waidi Shaibu ni wọn wa nibi eto ifilọlẹ naa.

Nigba to n gbe oriyin fun Aarẹ Tinubu, AbdulRazaq sọ pe gbogbo igba ni ikọlu awọn agbebọn aṣekupani maa n kọ awọn lominu, to si lawọn n wa ọna abayo.

O ṣapejuwe agbekalẹ ọhun gẹgẹ bi itura fun araalu, paapaa awọn agbegbe ti awọn agbebọn naa ti n ṣọṣẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI