Ọna abayọ tuntun ti wa lati koju awọn agbebọn aṣekupani ni Kwara - Gomina AbdulRazaq f'ọkan awọn araalu Woro ati Kaiama balẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, February 6, 2026

Ọna abayọ tuntun ti wa lati koju awọn agbebọn aṣekupani ni Kwara - Gomina AbdulRazaq f'ọkan awọn araalu Woro ati Kaiama balẹ

Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ṣsbẹwo siluu Kaiama ati Woro lati ba awọn ara agbegbe naa kẹdun lori ikọlu to waye laipẹ yii.

Nibi abẹwo ibanikẹdun ọhun ni gomina ti ṣeleri eto aabo to pe ye fawọn ara agbegbe.

Bakan naa lo tun fọkan awọn araalu balẹ wi pe Aarẹ Bọla Ahmẹd Tinubu ti ṣeleri lati gbe ikọ ọmọ ogun eleto aabo dide lati daabo bo ẹmi ati dukia araalu.

Ninu atẹjade ti akọwe iroyin gomina, Rafiu Ajakaye fi sita laipẹ yii, o jẹ ko di mimọ pe iru ikọlu ọhun ko nii waye mọ, pẹlu igbesẹ tuntun ti iṣakoso oun ṣẹṣẹ gbe.

Alẹ ọjọ Iṣẹgun ọsẹ yii lawọn agbebọn aṣekupani kọlu awọn agbegbe naa, ti wọn si pa awọn eeyan nipakupa, ti wọn tun ji awọn eeyan gbe lọ, koda wọn ba opo dukia jẹ.

Oru Ọjọru ni Gomina ṣsbẹwo si ilu Woro lati ba awọn eeyan kẹdun, ko too tun lọ ṣabẹwo s'awọn ara agbegbe Kaiama.

Nigba to n ba Emir ilu Kaiama, Alaaji Muazu Sheu Omar, Gomina jẹ ko di mimọ pe ẹdun ọkan ati ibanujẹ ni awọn ikọlu ọhun jẹ foun, to si lo bu ọgbẹ si ọkan oun.

Lara awọn to kọwọrin pẹlu gomina ni olori ile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa, 
Ọnarebu Salihu Yakubu-Danladi, awọn alakoso eto aabo, to fi mọ awpn alẹnulọrọ ninu ijọba.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI