Asiko aawẹ Lẹnti ati Ramadaani la le fi adura jagun lati gbogun ti awọn to ni ero buruku si ilọsiwaju Naijiria - Gomina AbdulRazaq - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, February 20, 2026

Asiko aawẹ Lẹnti ati Ramadaani la le fi adura jagun lati gbogun ti awọn to ni ero buruku si ilọsiwaju Naijiria - Gomina AbdulRazaq


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq tipinlẹ Kwara ti fi ikini rẹ ranṣẹ gbogbo awọn ẹlẹṣin Musulumi ati Kristẹni patapata lori aawẹ Lẹnti ati Ramadaani to wọle de.

Aawẹ naa to bẹrẹ lọjọ kejidinlogun, oṣu Keji, ọdun 2026, ni gomina ti gba gbogbo awọn to n gba aawẹ naa lamọran lati duro lori otitọ lasiko aawẹ ọhun.

Nigba to n sọrọ ninu atẹjade ikini ti akọwe iroyin rẹ, Rafiu Ajakaye fi sita lọjọ kẹtadinlogun, oṣu yii, o rọ gbogbo eeyan lati gba ifẹ ati alaafia laaye, ki wọn si fọwọsowọpọ ninu iṣọkan.

AbdulRazaq sọ pe nipa ifọwọsowọpọ iṣọkan nikan la fi le gbogun ti gbogbo igbimọ ibi, ati awọn ohun to le fa ilọsiwaju ipinlẹ naa ati ilẹ Naijiria lapapọ sẹyin.

“Adura maa n ṣi ferese ara-ọtọ silẹ fun eeyan lati sunmọ Adẹdaa nipa yiyago fun ẹṣẹ, lati fifun alaini lai nidi, ati awọn oniruuru iwa rere. O tun maa n ṣe iranwọ fun eniyan lati ara rẹ ṣe niwaju Adẹdaa,” gomina sọ bẹẹ. 

Gomina wa gbadura pe ki Ọlọrun gba gbogbo adura ati otitọ awọn araalu ninu oṣu mimọ naa, to si tun rọ awọn ẹlẹṣin mejeeji lati gbadura, ki wọn ṣiṣẹ pẹlu ijọba lati ṣe iranlọwọ to yẹ fun awọn alaini.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI