Iṣẹ tiata gbe Damilola Oni, Femi Branch at'awọn miran wọ London - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, February 20, 2026

Iṣẹ tiata gbe Damilola Oni, Femi Branch at'awọn miran wọ London


"O ṢEUN LONDON!!! 🔥🔥🔥🔥🔥🔥", eyi ni ọrọ ti gbajugbaja oṣere tiata nni, Damilola Oni fi ki gbogbo awọn ololufẹ rẹ niluu London lẹyin to pari ere ori-itage kan to kopa ninu rẹ.

"The Throne of Ashes" ni wọn pe akori ere ori itage naa, eyi toun pẹlu akẹgbẹ rẹ, Femi Branch ati awọn miran jọ ṣe.

Nigba to n kede eyi loju opo ayelujara rẹ, Damilola Oni jẹ ko di mimọ pe idunnu nla lo jẹ foun wa niluu London.

"Nko ni ọrọ lati fi ṣapejuwe iru ifẹ ti mo ni imọlara rẹ lati bi ọjọ meloo sẹyin, o duro digbi, aridaju, aiṣẹtan pẹlu otitọ. Gbogbo ẹya kaakiri agbaye ni mo dupẹ lọwọ wọn, mo dupẹ lọwọ gbogbo eeyan ti wọn wa wo THE THRONE OF ASHES, o dara pupọ nitori pe ẹ darapọ. Ẹ ṣeun nitori pe ẹ nifẹ ọmọ kekere yii gidigidi, o si jẹ ọpọlọpọ nnkan fun mo. Maa tun pada rii yin. ỌMỌỌBABINRIN OLUKEKE.. O digba ❤️"



No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI