Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ṣabẹwo ibanikẹdun si sipinlẹ Niger lati ba gomina ati awọn araalu kẹdun ikọlu awọn agbebọn to waye laipẹ yii.
Alaga ẹgbẹ awọn gomina nilẹ Naijiria, Abdulrazaq nibi abẹwo naa si Gomina Mohammed Umaru Bago kọminu lori ikọlu naa to waye niluu Borgu, to wa nipinlẹ naa.
O ni ipenija nla to ba ni lọkan jẹ ni, to si ni iwa buruku ti awọn agbebọn naa n hu ni gbogbo igba lo n ṣokunfa iku ọpọ araalu, ti wọn si tun n npadanu dukia.
Siwaju sii lo jẹ ko di mimọ pe ọpọ araalu ni wọn ti sọ di alainile lori, eyi to lo ku diẹ kaato.
O wa rọ gomina ati awọn araalu lati mu ọkan, to si ni ẹgbẹ gomina ilẹ Naijiria yoo ṣiṣẹ papọ lati tubọ maa gbogun ti awọn ọdaran loorekoore.
No comments:
Post a Comment