Gbọngan ipade nla lalẹhu ni Kwara, awọn agbaṣẹṣe bẹrẹ iṣẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, February 27, 2026

Gbọngan ipade nla lalẹhu ni Kwara, awọn agbaṣẹṣe bẹrẹ iṣẹ


Awọn agbaṣẹṣe ti bẹrẹ kikọ gbọngan ipade nla ti wọn pe ni Convention Centre, eyi ti ijọba ipinlẹ Kwara buwọ lu laipẹ yii.

Akẹwejẹ tiluu Aran-Orin, Olayinka Michael Fafoluyi lo fidi iroyin naa mulẹ loju opo rẹ lọjọ Ẹti, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Keji, ọdun 2026.

Fafoluyi tọpọ mọ si Solace, ẹni to jẹ amugbalẹgbẹ agba pataki fun Gomina AbdulRahman AbdulRazaq lori eto iroyin igbalode sọ pe ijọba ti fa akanṣe iṣẹ naa le awọn agbaṣẹṣe lọwọ.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI