Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ ti foju afurasi meji kan ti a gbọ pe wọn ko niṣẹ meji ju iṣẹ darandaran lọ ba ile-ẹjọ lori ẹsun ole jija.
Ọjọ Aje oni, ni ọlọpaa foju awọn mejeeji ba ile-ẹjọ Majisireeti to wa lagbegbe Iyaganku niluu Ibadan, ipinlẹ naa.
Abubakar Lawal, ẹni ọdun mejidinlogun ati Ibrahim Abubakar, ọmọ ogun ọdun lawọn mejeeji ti a gbọ pe wọn ji maalu kan ti owo rẹ ko ni din ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹrin (N700,000) naira.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, abule kan ti wọn n pe ni Odinrin to wa ni Ido, Ibadan ni awọn mejeeji yii ti ọlọpaa fẹsun meji ọtọọtọ to nii ṣe pe igbimọ papọ ati ole jija kan, ti wọn si sọ pe awọn ko jẹbi.
Nigba to n fẹsun kan wọn niwaju ile-ẹjọ, Agbefọba Iyabo Oladoyin, sọ pe awọn meji wọnyi ati awọn miran to ti na papa bora ni wọn jọ jalẹ naa lọjọ kejila, oṣu Keji, ọdun 2026 ni nnkan bi agogo marun-un owurọ.
O sọ pe abule Kaguo to wa ni Ido ni wọn ti ji maalu naa salọ, ko to di pe iwadii pada tu aṣiri wọn.
Bakan naa lo jẹ ko di mimọ pe ọkunrin kan to n jẹ Yusuf Ibrahim, to si ni ẹsun naa tako abala 390 ati 516 ninu iwe ofin ọdaran tipinlẹ Oyo ti ọdun 2000.
Nigba to n sọrọ, Onidajọ T. G. Daodu, paṣẹ pe ki wọn gba beeli awọn afurasi naa pẹlu idaji miliọnu kan naira ati oniduro kọọkan, bẹẹ lo sun igbẹjọ siwaju di ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹta, ọdun yii.

No comments:
Post a Comment