Gomina ipinlẹ Kaduna tẹlẹri, Nasiru El-Rufai ti kede pe oun ti de ọdọ ajọ to n gbogun ti ṣiṣẹ owo ilu kumọkumọ ati iwa ajẹbanu lorileede Naijiria, Economic and Financial Crimes Commission, EFCC.
El-Rufai sọ pe oun ṣetan lati dahun ibeere ajọ EFCC, gẹgẹ bi iwe ti wọn fi ranṣẹ soun.
Laipẹ yii ni ajọ EFCC fiwe ranṣẹ si alẹnulọrọ ẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress, ADC, lori ẹsun iwa ajẹbanu ti wọn fi kan iṣakoso rẹ.
Ọpọ awọn alatilẹyin El-Rufai ni wọn tẹle e lọ si ileeṣẹ EFCC lonii, ọjọ Aje, lati gbaruku tii.
Bi ẹ ko ba gbagbe, l'Ọjọbọ, ọsẹ to kọja ni awọn ẹṣọ aabo gbiyanju lati gbe agba oloṣelu naa ni papakọ ofurufu Nnamdi Azikiwe, ṣugbọn ti ko gba fun wọn.
Lẹyin eyi lo ṣe ifọrọwerọ pẹlu awọn akọroyin, to si fẹsun kan oludamọran pataki lori eto aabo, Nuhu Ribadu wi pe oun lo wa nidi bi wọn ṣe fẹẹ gbe oun.

No comments:
Post a Comment