Ẹgbẹ awọn gomina Naijiria kẹdun ikọlu Niger ati Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, February 16, 2026

Ẹgbẹ awọn gomina Naijiria kẹdun ikọlu Niger ati Kwara


Ẹgbẹ awọn gomina nilẹ Naijiria ti kọminu lori awọn ikọlu agbebọn aṣekupani to waye nipinlẹ Niger ati Kwara laipẹ yii, ti wọn si ba gbogbo awọn to farakaaṣa ikọlu naa kẹdun.

Ẹgbẹ naa labẹ aburada NGF sọ pe ẹdun ọkan ni ikọlu naa jẹ fun wọn, ati pe awọn nigbagbọ pe gbogbo ikọlu aṣekupani ọhun yoo dopin laipẹ.

Ọjọ Abamẹta to kọja yii ni awọn agbebọn aṣekupani ṣe ikọlu kaakiri agbegbe mẹta ọtọọtọ, iyẹn Tunga-Makeri, Konkoso ati Pissa to wa nipinlẹ Niger, nibi ti ọpọ eeyan ti ku.

Yatọ si ọpọ awọn eeyan to padanu ẹmi wọn, a tun gbọ pe pupọ awọn ara agbegbe ọhun ni wọn jigbe salọ.

Ninu atẹjade ti Gomina AbdulRahman AbdulRazaq tipinlẹ Kwara, ẹni to jẹ alaga ẹgbẹ naa fi sita lọjọ Aiku, ọjọ kẹẹdogun, oṣu Keji, ọdun 2026, o ni kii ṣe ohun to dun mọ awọn ninu lati padanu araalu.

Bakan naa lo tun ba awọn ara agbegbe Woro to wa nijọba ibilẹ Kaiama, nipinlẹ Kwara kẹdun lori ikọlu t'awọn agbebọn naa ṣe.

“A fi ọrọ ibanikẹdun wa ranṣẹ si awọn mọlẹbi to padanu awọn eeyan wọn ninu ikọlu to bani lọkan jẹ, bẹẹ la si gbadura pe awọn ti wọn jigbe yoo pada sile layọ ati alaafia,” atẹjade naa sọ bẹẹ.

O wa fidi rẹ mulẹ pe gbogbo igbesẹ to n lọ lọwọ lati koju iṣoro eto aabo yoo so eso rere, to si lawọn yoo bori ni ikẹyin.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI