Ohun kan ṣoṣo to wa lọkan mi bayii, ni lati le Tinubu danu lọdun 2027 - El-Rufai pariwo sita - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, February 13, 2026

Ohun kan ṣoṣo to wa lọkan mi bayii, ni lati le Tinubu danu lọdun 2027 - El-Rufai pariwo sita


Gomina tẹlẹri nipinlẹ Kaduna, Malam Nasir El-Rufai ti sọ pe oun ko ni erongba meji to kọja boun yoo ṣe le Aarẹ ilẹ Naijiria, Aṣiwaju Bola Ahmed Tinubu kuro nipo naa lọdun 2027, to si rọ gbogbo awọn olori ẹgbẹ alatako lati fimọ ṣọkan nipa gbigbajumọ bi wọn yoo ṣe gbajọba lọwọ APC.

El-Rufai lo sọrọ naa lasiko to ṣabẹwo fi aarẹ ilẹ Naijiria nigba kan ri, Alaaji Atiku Abubakar, lẹyin ti awọn eleto aabo gbiyanju lati gbe e ni papakọ ofurufu, lẹyin to de lati irin ajo ilẹ okeere to lọ laipẹ yii.

O ni iṣẹlẹ to ṣẹlẹ soun ni papakọ ofurufu naa ti fun oun ni okun lari tako iṣakoso to wa lori ipo lasiko yii.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, o ni, “Ohun to ṣẹlẹ lonii tun ti jẹ ki ipinu mi duro digbi. A ni lati maa ṣiṣẹ, ki a si ma ṣe sinmi titi di oṣu Kẹta, ọdun 2027, nigba ti a maa yọ ijọba yii kuro ni ipo.”

O ṣapejuwe ohun to ṣẹlẹ ni papakọ ofurufu naa gẹgẹ bi ohun to ku diẹ kaato, eyi ti wọn ko nilo, ti ko si ba ofin mu.

El-Rufai ni ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu, ICPC lo awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ lati da oun duro, lai kọkọ fi iwe ranṣẹ si oun, to si ni ko ba ofin mu.

Siwaju sii lo ni ṣaaju asiko naa ni ajọ EFCC ti kọkọ fi iwe ranṣẹ soun lati yọju si wọn fun ibeere, to si loun ko si nilẹ Naijiria lasiko naa, ati pe agbẹjọro oun da wọn lohun, to si loun yoo yọju si wọn lagogo mẹwaa ọjọ Aje to n bọ.

“Gbogbo ohun ti mo n beere fun ni iwe ipe, maa si yọju si wọn,” O sọ bẹẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI